Eso pele l’aye gba,
Eso pele l’ejo n gungi agbon,
Jeje si l’adie nse lori eyin.
Se eye toba fo lafoju
O seese ko fo koja ite re lo.
Aja toba loun mona ju olode
Ati sonu re lon sunmo tosi.
Eyin e wo alagemo to nlo jeje,
Sebi o ni iyi ati eye
Ju opolo to n san ara re mole.
Se owo ni o fe ni?
Tabi o fe de ipo giga?
Eko to gbona n fe suuru ore mi.
Kira kita kan ko kuku dola,
Ka sise bi eru ko si da nkan kan,
Oba Oluwa nikan lon gbe niga.
Opo loti fipa wowo,
Iru won ni kii lowo dojo ale;
Opo losi ti r’oko ebo koto bimo,
Iru won ni kii je ounje omo won.
Se eni toba fikanju la obe to gbona
Kole mo adun towa ninu obe.
Agope to loun o fikanju sokale
O seese ko so si ajule orun.
A sare tete kan ko kuku ni koja ile,
Beeni aringbere koni sun sona.
Mase sare koja igba tire lo,
Mase kanju ju Olorun Oba lo.
Suuru l’aye gba ore mi,
Oni suuru ni fun wara kiniun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Contact Olaoye Online

 For inquiries, questions, requests and information

Type Your Keywords: