Talo mojo ola?
Talo matisun eda?
Talo mori olola nigba ewe?
Sebi riro ni teniyan,
Sise nbe lowo Olorun Oba
Ojo tosu le maro
Ki Oba oke fi fe afefe
Oorun to si mu janjan le parada
Ki oju orun tun maa da omi
Aseyi o wuu ni Oluwa
Eda kan kosi mona to maa gba.

Eyin alagbara aye gbogbo
Eyin asofin ile agbaye
Eba rora feso jaye
Nitoripe atore atika ikan kii gbe
Erora se nitori eyin ola
Eyin efi aare olorikunkun se arikogbon
Oun loni ibo ni Olorun wa
To ngun omo eniyan bi eni gun esin
To npa eniyan bi eni pa eera
To si l’oun maa joba titi aye
Eyin e wo igbeyin asebi
E wo ikun re to n jogede to n redi
Se ikun ko mo pe oun todun lon pani
Aseyin wa aseyin bo
Ina dile leyin asunsu je
Okete bo iru mo are lowo
Sebi awon toti dajo iku fun
Awon to ti ran lo soko ewon
Awon lo pada wa joba leyin iku re
Talo mojo ola?

Ore taye ba n ye o loni
Mase foju tenbele enikan
Mase fiwa ika je omo otosi niya
Igi kekere ti a foju tinrin ni
O le digi araba eleso lojo ola
Se ile ola ni oti wa?
Tabi o wa nipo atata
Iwo mase fomo talaka se yeye
Akuku ti romo Oba to deru
Ati ri iwofa to te opa ileke
A si ti ralakisa to kole iyebiye
Iyanu ni Oba Oluwa
Oun nikan losi lee so ojo ola.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Contact Olaoye Online

 For inquiries, questions, requests and information

Type Your Keywords: